ORIKI IBEJI
NI EDE YORUBA
Ejire Ara Isokun
Edun A gbori igi reeferefe
winini winini loju orogun
Eji woro loju iya e
O be Kisi be kese
O be sile elekisa
O so o dalaso
Okan mo no n o bi
Eji lo wole to mi
But mi ki n ba o rele
Yin mi kin pada leyin re
Nijo Ejire to daye ko jale ri
Oju oloko ni se je tie
Mo lepo Nile
Mo lewa loode
Ejire eelaki maabo lodo mi
Ireke mi ree
Aadun mi ree
Mo fe bo Ibeji Òro
Oniruuru Omo lo nbe laye
Ninu Omo to je abami
La gbe ri Ibeji laarin won
Eni Ejire nwuu bi
Ki o yaa niwa tutu
Tori pe osonu Ile ko bi Ejire
Oninuure ni bedun
Ejire okin maa so mi lokun Lona ofun
Iya onikaluku won o so kale
Won abimo won Okan soso pere
Eni oninuure ni Olorun Oba nfun lore
Eyin ko mo pe ore lejire Ara Isokun
lyawo mi lejo
Emi naa Le sodi wuke
Ejire oriyaki maa bo lodo wa
Atike atige laa fii sike Ibeji
Atowo atiyi lejire Fi sike Eni
Oga lejire oriyaki laarin awon Omo to nbe laye gbogbo
ENGLISH VERSION
Twins, the offspring of Isokun
Nothing or useless children amongst the polygamist
Real Children to the Mother
They branched to the home of ragged persons and change their lie to better
I ought to give birth to only one child
fortunately, a set of twin. comes my way
Maltreat me, so that I will continue following you
If you praise me, I will turn back
Ape on the tree.
Comments
Post a Comment